Feed Blog Circles Pages Dashboard
Create Post Create Blog Create Alchemist Create Circle Create Page
Oturupon Meji

Oturupon Meji

Odu Ifa — Sacred Verse of the Oracle
Odu Ifa BODE Oracle 3 Languages Sacred Pattern
Listen
48 views Updated Oct 28, 2026 fafore.com/odu/oturupon-meji
Read in: English Yoruba Español Português Français Chinese Russian German Arabic
Odu Ifa Sacred Divination Pattern

The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray

1
Ese Kinni
Ese Kinni

Ase — Ifa Spiritual Message

Ifa ni ohun pe ire iyi fun eleyi ki onitohun o sibo ori re nitori agbega kio si feran omo la keji re gege bi ara re.

Ese — Yoruba Verse

Bi mose fe ri ni mo fe ki ore mi o ri

Adifa fun olomon ateni ore kore

Igba ti n tode orun bo waye

Ebo ni won ni ko se

O gbe bo ni be o rubo

Nje, eni timo wu oba loje

Orisa jeni ti mowu o wumi

Eni ti mowu oba loje.

Ebo — Sacrifice (Etutu)

  • Eku kan
  • Eja kan
  • Abodie kan
  • Epo
  • Eko
  • Obi
2
Ese Keji
Ese Keji

Ase — Ifa Spiritual Message

Ifa ni oun pe ire omo fun eleyi pe oju omo nipon, ifa pe kolo bo Osun pelu adire agada.

Ese — Yoruba Verse

Bebe o ke hin

Bebe o ke ohun

Adifa fun oturu

Ti o pon meji lekan

Ebo ni won ni kose

O si gbebo nibe o rubo

nje igba oturupon meji

lara ro awo.

Ebo — Sacrifice (Etutu)

  • Abo adie meji
  • Akuko kan
  • Epo
  • Eko
  • Obi
3
Ese Keta
Ese Keta

Ase — Ifa Spiritual Message

Ifa ni ki eleyi o rubo isegun pe awon kan ni won gbogun ti eleyi, ifa pe ebo ni kose.

Ese — Yoruba Verse

Akara ni ko kuta lojude opon

Adifa fun ayinrin

Ti se omo won lojude iwoya

Igba ti n be laarin ota

Ebo ni won ni ko se

O si gbebo ni be o rubo

Nje oni apa ayinrin

Ola apa ayinrin

A le pa ayinrin mon tuu

Tutun la n tu ayinrin.

Ebo — Sacrifice (Etutu)

  • Eran oruko kan
  • epo
  • Eko
  • Obi
4
Ese Kerin
Ese Kerin

Ase — Ifa Spiritual Message

Ifa pe ki eleyi o rubo isegun ki osi lobo awon olorun re dara dara kio si rubo pe ohun yio ba segun ki osi lo bo ifa pelu eku eja adire eran ewure.

Ese — Yoruba Verse

Pepe lawo ile
Atita lawo ode
Alapa n dede lokole tan lokoju re si gbagede olofin
Beni kofi kan omi be ni ko fi kan oke
Adifa fun Oyepolu
Ti se omo isoro nife
Baba re ku o fi sile ni lenje lenje
Iya re ku ofi sile ni lenje lenje
Won wa ko ohun oro le
O bu puru sekun
Ebo ni won ni ko se
O gbebo nibe o rubo
Nje epo ni won ko ko tale
Emi o mon isoro orun
E ya wa gba oro ta se
Omi oti eku eja eye eran ni won ko si lee
Emi o mon isoro orun
Eya wa gba oro ta se.

Ebo — Sacrifice (Etutu)

  • Eku kan
  • Eja kan
  • Abodie kan
  • Ewure kan
  • Epo
  • Eko
  • Obi
  • Oti

Awure — Alchemist Formula

Yoruba

Ao toju erupe yaya ogan ao toju ewe awede ao wa po mon ose dudu ao wa fi omi agbon po titi ti yio fii de ao wa mon fii we.

Isegun — Alchemist Formula

Yoruba

Ao mu ewe segun sete pelu ewe alupaida ao gun mon ose dudu ao wa fi maa we fun ojo meje.

Videos

Watch Oturupon Meji teachings on our channel.

Explore Ifa

Oturupon Meji is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Alchemist formulas (alchemical remedies).

Odus that share the same family or pairing include: Oturupon Ogbe, Oturupon Oyeku, Oturupon Iwori, Oturupon Odi.

← Browse all 256 Odu Ifa  |  Seek Divination

Reflections & Testimonies

0 reflections shared

Be the first to share a reflection on Oturupon Meji Odu.