Listen
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa pe ire omo fun eleyi, ifa pe oju omo ni pon, ifa ni kio pa afiju ti kio le badi olomo laye kio si lo bo ifa pelu elede kan.
Ese — Yoruba Verse
Ateyin ayinte
Adifa fun Elede
Tiise yeye odo
Igbati mo mi oju so gbere omo
Ebo ni won ni ko se
Ogbebo ni be o rubo
Nje omo yoyo ni todo
Omo to siwaju
Omo to seyin omo yoyo ni todo
Adifa fun Elede
Tiise yeye odo
Igbati mo mi oju so gbere omo
Ebo ni won ni ko se
Ogbebo ni be o rubo
Nje omo yoyo ni todo
Omo to siwaju
Omo to seyin omo yoyo ni todo
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Odidi elede kan
- Akuko adie kan
- Epo
- Eko
- Obi
2
Ese Keji
Ese Keji
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni oun pe ire gbogbo fun eleyi pe ebo ni ko se, Ifa pe ki eleyi o si mon bawon ja si nkan ogun tori nkan naa yio pada to si, kio lobo ori re pelu eye etu kan kio si fi eye etu kan rubo.
Ese — Yoruba Verse
Poro bayi
Ala bayi
Adifa fun ladebu
Tii se yeye oke
Igba ti momi oju sogbere aje
Ebo ni won ni ko se
Osi gbebo ni be o rubo
Nje aje ile yii n ko o toke ni
Aya ile yii n ko o, toke ni
Oke lotu wa
Toke toke leye etu ke
Ala bayi
Adifa fun ladebu
Tii se yeye oke
Igba ti momi oju sogbere aje
Ebo ni won ni ko se
Osi gbebo ni be o rubo
Nje aje ile yii n ko o toke ni
Aya ile yii n ko o, toke ni
Oke lotu wa
Toke toke leye etu ke
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Eye etu meji
- Epo
- Eko
- Obi
3
Ese Keta
Ese Keta
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni ki eleyi orubo pe ara ko ro eleyi, Ifa pe konitohun rubo fun ire gbogbo, Ifa ni ki eleyi o lo te ifa ki ara o le baro.
Ese — Yoruba Verse
O re oo
Ko re mi
Adifa fun ire
Ti lo le te meji lodo
Ebo ni won ni ko se
Osi gbebo ni be o rubo
Nje igba irete te meji
Ni ara ro awo.
Ko re mi
Adifa fun ire
Ti lo le te meji lodo
Ebo ni won ni ko se
Osi gbebo ni be o rubo
Nje igba irete te meji
Ni ara ro awo.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Eku meji
- Eja meji
- Abodie meji
- Epo
- Eko
- Obi
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni oun pe ire gbogbo fun eleyi, ifa pe ki eleyi o lo di mon ifa daradara pe eleda re ki ro ko ki yenaa ise ijoko ni eleda re mon se, kio bo ifa pelu ewure.
Ese — Yoruba Verse
Ero yanuu fodo kete
Adifa fun Atoka
Ti se ilari olodumare
Igba ti mo mi oju sogbere ire gbogbo
Ebo ni won ni kose
Ogbebo ni be orubo
Nje ilari oba oroko
Ilari oba orodo
Atoka wadi ilari
Olodumare.
Adifa fun Atoka
Ti se ilari olodumare
Igba ti mo mi oju sogbere ire gbogbo
Ebo ni won ni kose
Ogbebo ni be orubo
Nje ilari oba oroko
Ilari oba orodo
Atoka wadi ilari
Olodumare.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Eran ewure kan
- Epo
- Eko
- Obi
Awure — Alchemist Formula
Yoruba
Ao toju ewe ominni, ao wa lo po mon iyere, ao wa fi se igbin merin lepo ni yo, ao wa se adura si eni naa yio je obe yi.
Isegun — Alchemist Formula
Yoruba
Ao toju ori igbin, ao toju ewe apada, ati atare kan, o wa jo po ti a bajo tan ao wa fi sin gbere igba ati eyokan si aarin ori, ao fi iyoku fokomu lekan soso lori odo.
Explore Ifa
Irete Meji is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Alchemist formulas (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Irete Ogbe, Irete Oyeku, Irete Iwori, Irete Odi.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Irete Meji Odu.
