Listen
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni ohun pe ire gbogbo fun eniti odu yi jade fun, oni ohun ri ire gbogbo fun eleyi pe ebo ire gbogbo ni ko mo se.
Ese — Yoruba Verse
Pelebe idin awodi lawo laoke
Ka to mo ero agogo niriro riro
Adifa fun olofin
Eyi ti yio mon da obara meji rogba rogba loju opon ifa
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo ni be o rubo
Nje ifa ni n o laje molaje
Ebora alase obara meji
Abise wara wara
ifa ni oun nire gbogbo
Moni re gbogbo
Ebora alase obara meji abise wara wara.
Ka to mo ero agogo niriro riro
Adifa fun olofin
Eyi ti yio mon da obara meji rogba rogba loju opon ifa
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo ni be o rubo
Nje ifa ni n o laje molaje
Ebora alase obara meji
Abise wara wara
ifa ni oun nire gbogbo
Moni re gbogbo
Ebora alase obara meji abise wara wara.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Eku kan
- Eja kan
- Abo adire kan
- Epo
- Eko
- Obi
2
Ese Keji
Ese Keji
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni ki eleyi o rubo apesin, ifa ni eleyi o ri eni pe sin, pe ebo ni kose ki o le bari eni pe sin.
Ese — Yoruba Verse
Oro re ni kolagba ninu
Gbogbo eiye oko loda weese weese
Adifa fun eji obara
Eyi ti dala ji ki lola
Ebo ni won ni kose
O gbebo ni be o rubo
Nje eji obara ifa wa di olokun
ifa wa di Onide.
Gbogbo eiye oko loda weese weese
Adifa fun eji obara
Eyi ti dala ji ki lola
Ebo ni won ni kose
O gbebo ni be o rubo
Nje eji obara ifa wa di olokun
ifa wa di Onide.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Eran oruko kan
- Epo
- Eko
- Obi
3
Ese Keta
Ese Keta
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni ki eleyi o rubo ajinde ki osi rubo oye pe won yio pe eleyi si oye kan ki o mo sope ohun o fe o, tori oye naa yio sodi eni nla.
Ese — Yoruba Verse
Onibara
Olabara
Eyin o mo pe eye bara bara kii kate
Adifa fun orofo
Nijo ti lo leje ayaba eye larin igbe
Ebo ni won ni ko se
O gbebo nibe o rubo
Nje orofo momo de o ayaba eye
Eyin o mon pe afinju eye ki ka te.
Olabara
Eyin o mo pe eye bara bara kii kate
Adifa fun orofo
Nijo ti lo leje ayaba eye larin igbe
Ebo ni won ni ko se
O gbebo nibe o rubo
Nje orofo momo de o ayaba eye
Eyin o mon pe afinju eye ki ka te.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Pepeye meta
- Epo
- Eko
- Obi
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni ki eleyi o rubo emi re pe awon kan ni won gbe ogun buruku bo wa ka won mo yi, sugbon koru bo ki eleru o le gberu re kia kia, ki o si lo bo ifa nitori emi re.
Ese — Yoruba Verse
Kesekese leri
Kasakasa n bo leyin baba kesekese
Adifa fun agbigbo niwon ran
Ti so logun eba loro
Adi fa fun orunmila
Ni jo ti agbigbo fe gbe eru buruku le baba lori
Ebo ni won ni ki baba ose
Baba si gbebo ni be o rubo
Nje iku ni wa mi bo yi o
Agbigboni won ran gberu re
Awo o rowo ra ku, Awo o rowo rarun
Gbogbo ajogun ni wa awo bowa o
Agbigbo gberu re awo o rowo raku, Awo o rowo rarun.
Kasakasa n bo leyin baba kesekese
Adifa fun agbigbo niwon ran
Ti so logun eba loro
Adi fa fun orunmila
Ni jo ti agbigbo fe gbe eru buruku le baba lori
Ebo ni won ni ki baba ose
Baba si gbebo ni be o rubo
Nje iku ni wa mi bo yi o
Agbigboni won ran gberu re
Awo o rowo ra ku, Awo o rowo rarun
Gbogbo ajogun ni wa awo bowa o
Agbigbo gberu re awo o rowo raku, Awo o rowo rarun.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Eran ewure kan
- Akuko adire kan
- Epo
- Eko
- Obi
Awure — Alchemist Formula
Yoruba
A o toju ewe aki ka ti je ewe agbayun ao wa gun mon ose dudu, eni naa yio mon fi we.
Isegun — Alchemist Formula
Yoruba
Ao mun ewe alupaida mesan to baje okunrin ni odu yi jade fun, sugbon toba je obinrin, alupaida meje, ao wa mu eyo atare meje fun obinrin tabi mesan fun okunrin, ao jo po, ao wa fi sin gbere mesan fun okunrin, meje fun obinrin.
Explore Ifa
Obara Meji is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Alchemist formulas (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Obara Ogbe, Obara Oyeku, Obara Iwori, Obara Odi.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Obara Meji Odu.
