Listen
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni oun pe ire isegun fun eni ti odu Ogundaji ti an pe ni Ogunda meji jade fun, Ifa pe ebo ni kose kio si lo fi eja abori meji boo ogun.
Ese — Yoruba Verse
Ogundaji awo ibon
Lo sefa fun ibon
Nigba ti nbe laarin ota
Ebo ni won ni kose
O gbebo nibe orubo
Nje enu ti ibon fi n fohun
Ni n fi segun.
Lo sefa fun ibon
Nigba ti nbe laarin ota
Ebo ni won ni kose
O gbebo nibe orubo
Nje enu ti ibon fi n fohun
Ni n fi segun.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Akuko adire kan
- Eja abori meji
- Epo
- Eko
- Obi
2
Ese Keji
Ese Keji
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni oun pe ire gbogbo fun eni ti odu yi jade fun, ifa pe ebo ni ko se, Ifa ni komo se ore dara dara kio si fi eye etu kan bo ori re ki o fi akuko kan rubo.
Ese — Yoruba Verse
Ore lope
Ika kosunhan
Adifa fun Ajanaa
Ni jo ti lo le je oloko lai ba won tan
Ebo ni won ni ko se
O gbebo ni be orubo ni be
Nje kini o fi Ajanaa joloko
Ohun rere lo fi Ajanaa joloko
Ohun rere.
Ika kosunhan
Adifa fun Ajanaa
Ni jo ti lo le je oloko lai ba won tan
Ebo ni won ni ko se
O gbebo ni be orubo ni be
Nje kini o fi Ajanaa joloko
Ohun rere lo fi Ajanaa joloko
Ohun rere.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Eye etu kan
- Akuko adie kan
- Epo
- Obi
- Eko
3
Ese Keta
Ese Keta
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni ohun pe ire omo fun eniti o da odu Ogunda Meji ti an pe ni Ogundaji, Ifa pe oju omo ni pon eleyi, Ifa ni ebo ni ko se kio si lobo orisa pelu igbin merin.
Ese — Yoruba Verse
Abemonle ekan
Abojuregunregun
Adifa fun ori ti n sunkun omo rode Ipo
Lodi fa fun oyin ti sunkun omo rode Ofa
Ebo ni won ni ko se
O gbebo ni be orubo nibe
Nje oyin roguun oyin bi ogun
Won ni ki oyin o ru ogbon
Oyin bi ogbon
Ero ipo
Ero ofa
Eyin o mo pogun omo kotori.
Abojuregunregun
Adifa fun ori ti n sunkun omo rode Ipo
Lodi fa fun oyin ti sunkun omo rode Ofa
Ebo ni won ni ko se
O gbebo ni be orubo nibe
Nje oyin roguun oyin bi ogun
Won ni ki oyin o ru ogbon
Oyin bi ogbon
Ero ipo
Ero ofa
Eyin o mo pogun omo kotori.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Igbin merin
- Eku kan
- Eja kan
- Abo adire kan
- Epo
- Eko
- Obi
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni oun pe ire isegun fun eniti o da Ogunda Meji ti an pe ni Ogundaji , Ifa ni ki eleyi o ru bo, ki o si lo bo ifa pelu eran ewure.
Ese — Yoruba Verse
Orekojonaa seefin
Adifa fun Orunmila
Nijo ti lo le gba obinrin kan
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Nje oro ta ro sun ale ana
Mo fi soti mu gbere fun
Mofi oro yi mu taba gbere fun.
Adifa fun Orunmila
Nijo ti lo le gba obinrin kan
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Nje oro ta ro sun ale ana
Mo fi soti mu gbere fun
Mofi oro yi mu taba gbere fun.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Eran ewure kan
- Epo
- Eko
- Obi
- Ewe taba
- Oti
Awure — Alchemist Formula
Yoruba
Ao mu abemonle ekan ati ewe osusu ao wa gun mon ose dudu eni naa yio wa maa fi we larolaro.
Isegun — Alchemist Formula
Yoruba
Ao toju ewe taba ao gun po mon ose ao wa fi oti oyinbo po ao wa tun fi ewe taba die ao wa tun da sinu oti oa mon mu oti yii ao si mon fi ose we.
Explore Ifa
Ogunda Meji is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Alchemist formulas (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Ogunda Ogbe, Ogunda Oyeku, Ogunda Iwori, Ogunda Odi.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Ogunda Meji Odu.
