Feed Blog Circles Pages Dashboard
Create Post Create Blog Create Alchemist Create Circle Create Page
Ofun Meji

Ofun Meji

Odu Ifa — Sacred Verse of the Oracle
Odu Ifa BODE Oracle 3 Languages Sacred Pattern
Listen
69 views Updated Oct 28, 2026 fafore.com/odu/ofun-meji
Read in: English Yoruba Español Português Français Chinese Russian German Arabic
Odu Ifa Sacred Divination Pattern

The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray

1
Ese Kinni
Ese Kinni

Ase — Ifa Spiritual Message

Ifa ni oun pe ire aiku fun eleyi, Ifa ni ki onitohun o rubo emi re, ko si fi ejo kun ebo ruu, ko si mu oti ni ojo tio ba da ifa yii daradara.

Ese — Yoruba Verse

Onaa gboroo lejo fi gun agbon
Adifafun orangun
Nijo ti won n pe lalade orun
Ebo ni won ni kose
O gbebo ni be orubo
Nje orangun o wa mon o
A ti ti orangun mo le

Ebo — Sacrifice (Etutu)

  • Akuko Adire meji
  • Ori Ejo
  • Oti
  • Obi
  • Epo
  • Eko
2
Ese Keji
Ese Keji

Ase — Ifa Spiritual Message

Ifa ni oun pe ire gbogbo fun eleyi pe ibikan ni eleyi lo yi, ifa pe koru bo kole ba ri re mu bo ni be, kio si lo bo ifa pelu eran ewure.

Ese — Yoruba Verse

Eruku toro ro
Eruku tara ra
Adifa fun eji orangun
Nijo ti sawo lo ile ilesan
Ebo ni won ni kose
Osi gbebo nibe o rubo
Nje igba eji orangun
Sawo dele ilesan loda laje
Eruku tororo o
Eruku tara ra
Igba eji orangun sawo dele ilesan
Lo do ni re gbogbo
Eruku toro ro
Eruku tara ra

Ebo — Sacrifice (Etutu)

  • Eran ewure kan
  • Epo
  • Eko
  • Obi
3
Ese Keta
Ese Keta

Ase — Ifa Spiritual Message

Ifa ni oun pe ire aya fun eleyi pe oju aya ni pon eleyi ebo ni ko se ko le ba di alaya kio si fi eku eja abodie bo ifa.

Ese — Yoruba Verse

Adeyeri Lawo alajiki
Adetutu Lawo aji feran rere lo
Adifa fun orunmila
Ni jo ti lo le gbaye tuntun ni yawo
Ebo ni won ni ko se
Osigbebo ni be orubo
Nje erigin alo logbaye tuntun ni yawo
aye ifa tutu o jomi lo.

Ebo — Sacrifice (Etutu)

  • Eku kan
  • Eja kan
  • Abodire kan
  • Epo
  • Eko
  • Obi
4
Ese Kerin
Ese Kerin

Ase — Ifa Spiritual Message

Ifa ni oun pe ire isegun fun eleyi ki eleyi o rubo isegun kio si lo bo ifa pelu eran elede odidi kan, ti won ba fe pa elede yii won yio tori re bo omi ki won o to pa.

Ese — Yoruba Verse

Bagbon osoro
Atidi bole
Ida soro teku bako
Bi alamu osoro
Atidi bo eba ogiri
Adifa fun korowo ti nbe laarin ota
Ebo ni won ni ko se
Osi gbebo ni be o rubo
Nje obalade toju ota bomi
Osuru suru
Obalade toju ota bomi
Osuru suru

Ebo — Sacrifice (Etutu)

  • Odidi elede kan
  • Epo
  • Eko
  • Obi

Awure — Alchemist Formula

Yoruba

Ao mu ewe eyin olobe die, pelu iyere ao fi se adire ta gee si ona meje tobaje obinrin mesan toba je okunrin, ki a to je obe yi o di igba ti owo bapa, tese pa, la le ni ao to je obe naa, ao wa la gbogbo obe naa.

Isegun — Alchemist Formula

Yoruba

Ao mu eran elede ao toju agbon ile kan, ao toju ako alangba kan, ao wa jo gbo gbo re papo mon ewe apada ao wa po mon ose dudu eni naa yio mon fi we laro laro.

Videos

Watch Ofun Meji teachings on our channel.

Explore Ifa

Ofun Meji is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Alchemist formulas (alchemical remedies).

Odus that share the same family or pairing include: Ofun Ogbe, Ofun Oyeku, Ofun Iwori, Ofun Odi.

← Browse all 256 Odu Ifa  |  Seek Divination

Reflections & Testimonies

0 reflections shared

Be the first to share a reflection on Ofun Meji Odu.