Listen
Odu Ifa Sacred Divination Pattern
The sacred Odu marks as cast on the Opele or Ikin divination tray
1
Ese Kinni
Ese Kinni
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni oun pe ire iyi fun eleyi, ifa pe ipo kan ni won fe fi lo eleyi, kio mon sope ohun ose o, kio le ba di eni iyi, kio si funnOri re ni eyele kan, ko fi borire.
Ese — Yoruba Verse
Okanran Kan ni hin
Okaran kan lohun
Adifa fun omu nijo ti lo le je olori larin ara
Ebo ni won ni kose
O gbebo nibe o rubo
Nje a momu je olori
Gbogbo omo eni
E mon mon wa ewa sin.
Okaran kan lohun
Adifa fun omu nijo ti lo le je olori larin ara
Ebo ni won ni kose
O gbebo nibe o rubo
Nje a momu je olori
Gbogbo omo eni
E mon mon wa ewa sin.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Eyele merin
- Epo
- Eko
- Obi
2
Ese Keji
Ese Keji
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa ni pe oun pe ire gbogbo fun eleyi, ebo ni ko se, papa julo kio mon moju to nkan ara re ju teni eleni lo.
Ese — Yoruba Verse
Aki n foju oloju sowo kajere
Adifa fun orunmila
Baba yio fi irinwo sowo
Yoo jere egberin oke
Ebo ni won ni kose
Ogbe bo ni be o rubo
Nje aje ni emi o ni legberin
Gbogbo e gbogbo e legberun
Ire gbogbo ni emi o ni legberin
Gbogbo e gbogbo e legberin.
Adifa fun orunmila
Baba yio fi irinwo sowo
Yoo jere egberin oke
Ebo ni won ni kose
Ogbe bo ni be o rubo
Nje aje ni emi o ni legberin
Gbogbo e gbogbo e legberun
Ire gbogbo ni emi o ni legberin
Gbogbo e gbogbo e legberin.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Akuko adie meji
- Epo
- Eko
- Obi
- Owo
3
Ese Keta
Ese Keta
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa pe oun pe ire isegun fun eleyi pe awon kan ni won gbe ogun ti eleyi, ifa pe ebo ni ko se kio si lo bo sango pelu akuko adire kan.
Ese — Yoruba Verse
O bale bopon gba riri
Ojo mon gba ni ro kangokango
Adifa fun Oni ti le feyin ju segun
Igba ti be ni rogun ota
Ebo ni won ni ko se
Ogbebo ni be o rubo
Nje ati egungun atorisa
Ko sorisa to le ba sango kogun.
Ojo mon gba ni ro kangokango
Adifa fun Oni ti le feyin ju segun
Igba ti be ni rogun ota
Ebo ni won ni ko se
Ogbebo ni be o rubo
Nje ati egungun atorisa
Ko sorisa to le ba sango kogun.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Akuko adie kan
- Epo
- Eko
- Obi
- Orogbo
4
Ese Kerin
Ese Kerin
Ase — Ifa Spiritual Message
Ifa pe ire gbogbo fun eleyi pe ibi kan ni eleyi n lo yi, korubo kole ba la ni ohun, kio si lo bo ifa pelu eku, eja, ati abodie ki aye ole ba gba ni ohun.
Ese — Yoruba Verse
Bi e lebo ope ni
Ase fin koye ni
Oro ti ko kan ni konuko lasoju
Adifa fun eji okanran
Ni jo ti sawo rele oun tile
Ebo ni won ni kose
Osi gbebo ni be o rubo
Nje eji okanran
Igba tode tile lodoba
Igba tode tile lo fe le wawon
Igba tode ti le lo to doba.
Ase fin koye ni
Oro ti ko kan ni konuko lasoju
Adifa fun eji okanran
Ni jo ti sawo rele oun tile
Ebo ni won ni kose
Osi gbebo ni be o rubo
Nje eji okanran
Igba tode tile lodoba
Igba tode tile lo fe le wawon
Igba tode ti le lo to doba.
Ebo — Sacrifice (Etutu)
- Eku
- Eja
- Abodie
- Akuko die
- Epo
- Eko
- Obi
Awure — Alchemist Formula
Yoruba
Ao mu ewe saworo pepe pelu iyere ao fi se eyin adire merin lepo ni yo, eni naa yio se adura si yio je.
Isegun — Alchemist Formula
Yoruba
Ao toju epo obo ao gun mon ose dudu ao wa to ju aso funfun aso pupa aso ayinrin ao wa mun meteta ao wa fi se kankan, eni naa yio fi we yio wa loso awon meteta yi sinu igbo rere.
Explore Ifa
Okanran Meji is one of the 256 sacred Odu Ifa — the corpus of divination verses that form the foundation of the Yoruba oracle system. Each Odu contains multiple Ese (verses) alongside their Ase (spiritual power), Ebo (sacrifice), and Alchemist formulas (alchemical remedies).
Odus that share the same family or pairing include: Okanran Ogbe, Okanran Oyeku, Okanran Iwori, Okanran Odi.
Reflections & Testimonies
Be the first to share a reflection on Okanran Meji Odu.
